Ìṣe àwọn Aposteli 2:25-28
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
25 (A)Dafidi tí wí nípa tirẹ̀ pé:
“ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo níwájú mí,
nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi,
a kì ó ṣí mi ní ipò.
26 Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀:
pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.
27 Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà òkú,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.
28 Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè,
ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’
Ìṣe àwọn Aposteli 2:31
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
31 (A)Ní rí rí èyí tẹ́lẹ̀, ó sọ ti àjíǹde Kristi, pé a kò fi ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ ni isà òkú, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.