Deuteronomi 32:21
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
21 (A)Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,
wọ́n sì fi ohun asán an wọn mú mi bínú.
Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;
èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀-èdè.
Romu 11:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìran aláìkọlà pín nínú ìgbàlà àwọn ọmọ Israẹli
11 (A)Ǹjẹ́ mo ní, wọ́n ha kọsẹ̀ kí wọn kí ó lè ṣubú? Kí a má ri i, ṣùgbọ́n nípa ìṣubú wọn, ìgbàlà dé ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, láti mú Israẹli jowú.
Read full chapter
Romu 11:14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
14 (A)bí ó le ṣe kí èmi kí ó lè mú àwọn ará mi jowú, àti kí èmi kí ó lè gba díẹ̀ là nínú wọn.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.