Gẹnẹsisi 46:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
11 Àwọn ọmọkùnrin Lefi:
Gerṣoni, Kohati àti Merari.
Eksodu 6:16-20
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
16 (A)Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn:
Gerṣoni, Kohati àti Merari.
Lefi lo ẹ̀tàndínlógóje (137) ọdún láyé.
17 Àwọn ọmọ Gerṣoni ni ìran wọn ni:
Libni àti Ṣimei.
18 Àwọn ọmọ Kohati ni:
Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.
Kohati lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé.
19 Àwọn ọmọ Merari ni:
Mahili àti Muṣi.
Ìwọ̀nyí ni ìran Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn.
20 (B)Amramu sì fẹ́ Jokebedi arábìnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jokebedi sì bí Aaroni àti Mose fún un.
Amramu lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.
Numeri 3:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí, Nadabu ni àkọ́bí, Abihu, Eleasari àti Itamari.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.