Gẹnẹsisi 47:29-31
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
29 (A)Nígbà tí àkókò ń súnmọ́ etílé fún Israẹli láti kú, ó pe Josẹfu, ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Bí mo bá rí ojúrere ni ojú rẹ̀ fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi, kí o sì ṣe ìlérí pé ìwọ yóò fi àánú àti òtítọ́ hàn sí mi. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Ejibiti, 30 Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo bá sinmi pẹ̀lú àwọn baba mi, gbé mí jáde kúrò ní Ejibiti kí o sì sin mí sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba mi sí.”
Josẹfu sì dáhùn wí pé, “Èmi ó ṣe bí ìwọ ti wí.”
31 Jakọbu wí pé, “Búra fún mi,” Josẹfu sì búra fún un. Israẹli sì tẹ orí rẹ̀ ba, bí ó ti sinmi lé orí ibùsùn rẹ̀.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.