Heberu 5:6
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 (A)Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibòmíràn pé,
“Ìwọ ni àlùfáà títí láé
ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”
Heberu 5:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 (A)Tí a yàn ní olórí àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ní ipasẹ̀ Melkisedeki.
Read full chapter
Heberu 6:20
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
20 (A)níbi tí Jesu, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ alábojútó àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.
Read full chapter
Heberu 7:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Jesu fẹ́ràn Melkisedeki
11 (A)Ǹjẹ́ ìbá ṣe pé pípé ń bẹ nípa oyè àlùfáà Lefi, (nítorí pé lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn gba òfin), kín ni ó sì tún kù mọ́ tí àlùfáà mìíràn ìbá fi dìde ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Melkisedeki, tí a kò si wí pé ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Aaroni?
Read full chapter
Heberu 7:15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà mìíràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melkisedeki.
Read full chapter
Heberu 7:21
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
21 ṣùgbọ́n ti òun jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nígbà tí Ọlọ́run wí fún un pé,
“Olúwa búra,
kí yóò sì yí padà:
‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé ni ipasẹ̀ ti Mekisédékì.’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.