Add parallel Print Page Options

Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.

Read full chapter

“Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tarsu ìlú kan ní Kilikia, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gamalieli ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì ní ìtara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní. (A)Mo sì ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn tí ń tọ ọ̀nà yìí dé ojú ikú wọn, mo dè tọkùnrin tobìnrin wọ́n, mo sì fi wọ́n sínú túbú, àní bí olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo àjọ àwọn alàgbà tí lè jẹ́ mi ní ẹ̀rí. Mo tilẹ̀ gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Damasku láti mú àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní dídè wá sí Jerusalẹmu, láti jẹ wọ́n ní yà.

“Bí èmi tí súnmọ́ etí Damasku níwọ̀n ọjọ́-kanrí, lójijì ìmọ́lẹ̀ ńlá láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí mi ká. Mo sì ṣubú lulẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan tí ó wí fún mi pé, ‘Saulu, Saulu èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’

“Mo sì béèrè pé, ‘Ta ni ìwọ, Olúwa?’

“Ó sì dá mi lóhùn pé, ‘Èmi ni Jesu tí Nasareti, ẹni tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí.’ Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi rí ìmọ́lẹ̀ náà nítòótọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀.

10 “Mo sí béèrè pé, ‘Kín ni kí èmí kí ó ṣe, Olúwa?’

“Olúwa sì wí fún mi pé, ‘Dìde, kí o sì lọ sí Damasku; níbẹ̀ ni a ó sì ti sọ ohun gbogbo fún ọ tí a yàn fún ọ láti ṣe.’ 11 Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi fà mí lọ́wọ́ wọ Damasku lọ nítorí tí èmi kò lè ríran nítorí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ náà ti fọ́ mi ní ojú.

12 “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Anania tọ̀ mí wá, ẹni tó jẹ́ olùfọkànsìn ti òfin, tí ó sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn Júù tí ó ń gbé ibẹ̀. 13 Ó sì dúró tì mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Arákùnrin Saulu, gba ìríran!’ Ní ẹsẹ̀ kan náà, mo sì ṣí ojú sí òkè mo sì lè rí i.

14 “Nígbà náà ni ó wí pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba wa ti yàn ọ́ láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ri Ẹni Òdodo náà, àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu rẹ̀. 15 Ìwọ yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn, nínú ohun tí ìwọ tí rí tí ìwọ sì ti gbọ́. 16 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, kín ni ìwọ ń dúró dè? Dìde, kí a sì bamitiisi rẹ̀, kí ó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù, kí ó sì máa pe orúkọ rẹ̀.’

17 “Nígbà tí mo padà wá sí Jerusalẹmu tí mo ǹ gbàdúrà ní tẹmpili, mo bọ́ sí ojúran, 18 mo sì rí Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ fún mi pé, ‘Kíá! Jáde kúrò ní Jerusalẹmu kánkán, nítorí wọn kì yóò gba ẹ̀rí rẹ nípa mi gbọ́.’

19 “Èmi sì wí pé, ‘Olúwa, àwọn ènìyàn wọ̀nyí pàápàá mọ̀ pé èmi ti lọ láti inú Sinagọgu kan sí èkejì láti máa sọ wọ́n sínú túbú àti láti máa lu àwọn tí ó gbà ọ́ gbọ́. 20 Nígbà tí a sì ta ẹ̀jẹ̀ Stefanu ẹlẹ́rìí rẹ sílẹ̀, èmi náà pẹ̀lú dúró níbẹ̀, mo sì ní ohùn sí ikú rẹ̀, mo sì ń ṣe ìtọ́jú aṣọ àwọn ẹni tí ó pa á.’

21 “Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, ‘Máa lọ: nítorí èmi ó rán ọ sí àwọn aláìkọlà lókèèrè réré.’ ”

Read full chapter

Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, Èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”

Read full chapter

“Àwọn Júù mọ irú ìgbé ayé tí mo ń gbé láti ìgbà èwe mi, láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi ní orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerusalẹmu. Nítorí wọ́n mọ̀ mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí sí i, wí pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìsìn wa tí ó lè jùlọ, Farisi ni èmi. Nísinsin yìí nítorí ìrètí ìlérí tí Ọlọ́run tí ṣe fún àwọn baba wa ni mo ṣe dúró níhìn-ín fún ìdájọ́. Ìlérí èyí tí àwọn ẹ̀yà wa méjèèjìlá tí ń fi ìtara sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru tí wọ́n ń retí àti rí i gbà. Ọba Agrippa, nítorí ìrètí yìí ni àwọn Júù ṣe ń fi mi sùn. Èéṣe tí ẹ̀yin fi rò o sí ohun tí a kò lè gbàgbọ́ bí Ọlọ́run bá jí òkú dìde?

(A)“Èmi tilẹ̀ rò nínú ará mi nítòótọ́ pé, ó yẹ ki èmi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun lòdì sí orúkọ Jesu tí Nasareti. 10 Èyí ni mo sì ṣe ni Jerusalẹmu. Pẹ̀lú àṣẹ tí mo tí gba lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, mo sọ àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mímọ́ sí inú túbú, nígbà tí wọ́n sí ń pa wọ́n, mo ní ohùn sí i. 11 Nígbà púpọ̀ ni mo ń fi ìyà jẹ wọ́n láti inú Sinagọgu dé inú Sinagọgu, mo ń fi tipá mú wọn láti sọ ọ̀rọ̀-òdì. Mo sọ̀rọ̀ lòdì sí wọn gidigidi, kódà mo wá wọn lọ sí ìlú àjèjì láti ṣe inúnibíni sí wọn.

12 “Nínú irú ìrìnàjò yìí ní mo ń bá lọ sí Damasku pẹ̀lú ọlá àti àṣẹ ikọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 13 Ni ọ̀sán gangan, ìwọ ọba Agrippa, bí mo ti wà ní ojú ọ̀nà, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run wá, tí ó mọ́lẹ̀ ju oòrùn lọ, ó mọ́lẹ̀ yí mi ká, àti àwọn tí ń bá mi lọ sì àjò. 14 Gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn tí ń fọ sì mi ni èdè Heberu pé, ‘Saulu, Saulu! Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ohun ìrora ní fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún!’

15 “Èmi sì wí pé, ‘Ìwọ ta ni, Olúwa?’

“Olúwa sì wí pé, ‘Èmi ni Jesu tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí. 16 (B)Ṣùgbọ́n dìde, kí o sí fi ẹsẹ̀ rẹ tẹlẹ̀: nítorí èyí ni mo ṣe farahàn ọ́ láti yàn ọ́ ní ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí, fún ohun wọ̀nyí tí ìwọ tí rí nípa mi, àti àwọn ohun tí èmi yóò fi ara hàn fún ọ: 17 Èmi yóò gbà ọ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Èmi rán ọ sí wọn nísinsin yìí 18 (C)láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’

19 “Nítorí náà, Agrippa ọba, èmi kò ṣe àìgbọ́ràn sì ìran ọ̀run náà. 20 Ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà ní Damasku, àti ní Jerusalẹmu, àti já gbogbo ilẹ̀ Judea, àti fún àwọn kèfèrí, kí wọn ronúpìwàdà, kí wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run, kí wọn máa ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ sì ìrònúpìwàdà. 21 Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù ṣe gbá mi mú nínú tẹmpili, tí wọ́n sì ń fẹ́ pa mí. 22 Ṣùgbọ́n bí mo sì tí ri ìrànlọ́wọ́ gbà láti ọ́dọ̀ Ọlọ́run, mo dúró títí ó fi di òní, mo ń jẹ́rìí fún èwe àti àgbà, èmi kò sọ ohun mìíràn bí kò ṣe ohun tí àwọn wòlíì àti Mose tí wí pé, yóò ṣẹ: 23 Pé, Kristi yóò jìyà, àti pé òun ni yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jíǹde kúrò nínú òkú, òun ni yóò sí kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti fún àwọn aláìgbàgbọ́.”

Read full chapter

Àwọn Israẹli tó ṣẹ́kù

11 (A)Ǹjẹ́ mo ní: Ọlọ́run ha ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù bí? Kí a má ri. Nítorí Israẹli ni èmi pẹ̀lú, láti inú irú-ọmọ Abrahamu, ni ẹ̀yà Benjamini.

Read full chapter

18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú. 19 (A)Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkára yín jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 20 Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú. 21 Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera!

Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú. 22 Heberu ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Israẹli ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Irú-ọmọ Abrahamu ní òun bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. 23 (B)Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkúgbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. 24 (C)Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. 25 (D)Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. 26 (E)Ní ìrìnàjò nígbàkúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin. 27 (F)Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́ òru nígbàkúgbà, nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú àwẹ̀ nígbàkúgbà, nínú òtútù àti ìhòhò. 28 Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọn n dúró tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ. 29 (G)Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná?

30 Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi. 31 Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké.

Read full chapter