Ìfihàn 6:12-13
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 (A)Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfà mo sì rí i, sì kíyèsi i, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; oòrùn sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òṣùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀; 13 (B)àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í.
Read full chapter
Isaiah 13:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 (A)Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn
kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn.
Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn
àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.
Joẹli 2:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 (A)Ayé yóò mì níwájú wọn;
àwọn ọ̀run yóò wárìrì;
oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn,
àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn.
Sefaniah 1:15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 Ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú,
ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú,
ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoro
ọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba,
ọjọ́ kurukuru àti òkùnkùn biribiri,
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.