Deuteronomi 27:2-8
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 Nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani sí inú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbé kalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun. 3 Kí ìwọ kí ó kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí ìwọ bá ti ń rékọjá láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ. 4 Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ebali, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun. 5 Kọ́ pẹpẹ síbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn. 6 Kí ìwọ kí ó mọ pẹpẹ pẹ̀lú òkúta àìgbẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí ìwọ kí ó sì máa rú ẹbọ sísun ni orí rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. 7 Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ. 8 Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.