Esekiẹli 23:6-9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 Aṣọ aláró ni a fi wọ̀ wọ́n, àwọn gómìnà àti àwọn balógun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà àwọn tí ń gun ẹṣin. 7 O fi ara rẹ̀ fún gbajúmọ̀ ọkùnrin Asiria gẹ́gẹ́ bí panṣágà obìnrin, o fi òrìṣà gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, 8 kò fi ìwà panṣágà tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Ejibiti sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.
9 “Nítorí náà mo fi i sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ará Asiria, tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.
Read full chapter
Lefitiku 19:15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 (A)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúsàájú sí ẹjọ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn: ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.