1 Johanu 3:7-10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín: ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo. 8 (A)Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni; nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí ó lè pa iṣẹ́ èṣù run. 9 (B)Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kì í dẹ́ṣẹ̀; nítorí tí irú rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀: kò sì lè dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé a ti ti ipa Ọlọ́run bí i. 10 Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ èṣù; ẹnikẹ́ni tí kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run.
Read full chapter
1 Johanu 4:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìfẹ́ Ọlọ́run àti ti àwa
7 (A)Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí a fẹ́ràn ara wa: nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àti gbogbo ẹni tí ó bá ní ìfẹ́, a bí i nípa ti Ọlọ́run, ó sì mọ Ọlọ́run.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.