Efesu 5:6-8
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. 7 Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn.
8 Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: Ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀:
Read full chapter
Daniẹli 7:8
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
8 (A)“Bí mo ṣe ń ronú nípa ìwo náà, nígbà náà ni mo rí ìwo mìíràn, tí ó kéré tí ó jáde wá ní àárín wọn; mẹ́ta lára àwọn ìwo ti àkọ́kọ́ sì fàtu níwájú u rẹ̀. Ìwo yìí ní ojú bí i ojú ènìyàn àti ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.
Read full chapter
Daniẹli 7:25
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
25 (A)Yóò sọ̀rọ̀ odi sí Ọ̀gá-ògo, yóò sì pọ́n ẹni mímọ́ lójú, yóò sì gbèrò láti yí ìgbà àti òfin padà. A ó fi àwọn ẹni mímọ́ lé e lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀, ní ọdún méjì àti ààbọ̀.
Read full chapter
Daniẹli 11:36
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ọba tí ó gbé ara rẹ̀ ga
36 “Ọba yóò ṣe bí ó ti wù ú yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, ju gbogbo òrìṣà lọ, yóò máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò-ṣe-é-gbọ́-létí sí Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run, yóò sì máa yege títí àkókò ìbínú yóò fi parí, nítorí ohun tí a ti pinnu yóò ṣẹlẹ̀.
Read full chapter
Ìfihàn 13:5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
5 (A)A sì fún un ni ẹnu láti má sọ ohun ńlá àti ọ̀rọ̀-òdì, a sì fi agbára fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni oṣù méjìlélógójì.
Read full chapter
Johanu 17:12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 (A)Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn ní ayé, mo pa wọ́n mọ́ ní orúkọ rẹ; àwọn tí ìwọ fi fún mi, ni mo ti pamọ́, ẹnìkan nínú wọn kò sọnù bí kò ṣe ọmọ ègbé; kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.